Jump to content

Sambisa Forest

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ẹ̀dà aṣeétẹ̀jáde kò ṣe é lò nínú, ó sì lè ní àṣìṣe àmúlò. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ṣe àtúnmúkójúùwọ̀n fún aṣèrántí-ojú-ìwé ẹ̀rọ-àṣàwárí, dákun, ṣàmúlò ìlò títẹ̀jáde ìpìlẹ̀ ti ẹ̀rọ-àṣàwárí dípò bẹ́ẹ̀.

Sambisa Forest jẹ́ igbó kan ní Ìpínlẹ̀ Bọ̀rnó, àríwá apá ìlà oòrùn Nàìjíríà. Ó wà ní gúúsù apá ìwọ oòrùn Chad Basin National Park, ó sì tó bí kilometer ọgọ́ta láti gúúsù ìlà-oòrùn Maiduguri, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Bọ̀rnó. Ilé Sambisa forest tó kilometer èjì dín ní okòó-lé-ní-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta(518).[1][2]

Ilẹ̀ Sambisa

Sambisa forest wà ní àríwá apá ilà-oòrùn ti ìwọ oòrùn Sudanian Savanna àti ní gúúsù Sahel Savannah àti bi kilometer ọgọ́ta láti gúúsù ìlà-oòrùn Maiduguri, olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Borno.[3] Ilẹ̀ rẹ̀ gba díẹ̀ nínú àwọn Ìpínlẹ̀ Borno, Yobe, Gombe, Bauchi, lára ilẹ̀ Darazo, Jigawa, àti ara ilẹ̀ àríwá Ipinle Kano.[4][3] Ó wà lábẹ́ ìdarí Àwọn Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Nàìjíríà ti Askira/Uba ní apá gúúsù rẹ̀, Damboa ní apá ìwọ̀ oòrùn gúúsù rẹ̀, àti Konduga òun Jere ní apá ìwọ̀ òórùn rẹ̀.[3]

Àwọn ènìyàn so igbó náà ní Sambisa forest nítorí pé ìlú kan wà ní ẹgbẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Sambisa.

Ìkọ̀ Boko Haram

Igbó Sambisa, pàápàá jùlọ ibi ilẹ̀ àpáta tí ó wà ní Gwoza lẹ́gbẹ àlà Cameroon, jẹ́ ibi tí àwọn Ìkọ̀ Boko Haram fi ń ṣelẹ́, ìdánilójú sì wà pé ibè ni wọ́n kó àwọn ọmọ tí wọ́n jí gbé ní Chibok ní oṣù kẹrin ọdún 2014.[5][6][7][8]

Ní ọdún 2015, àwọn ọmọ ológun Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ sí ń dójú ìjà kọ Boko Haram nínú igbó náà, ṣùgbọ́n wọ́n rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí wọ́n ri pé àwọn Ikọ̀ Boko Haram ti gbin àwọn àdá olóró síbẹ̀ àti pé àwọn ikọ̀ Boko Haram mo bí ilẹ̀ náà ṣe rí ju àwọn ọmọ ológun Nàìjíríà lọ.[9] Pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo èyí, ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2015, àwọn ibùdó Boko Haram mẹ́rin ní igbó Sambisa ni àwọn ọmọ ológun gbà tí wón sì tú àwọn obìnrin tí ó fèrè tó ọ́ọ̀dúnrún sílẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn yìí kìí se àwọn ọmọ Chibok tí Boko Haram jí gbé.

Àwọn Ìtọ́kasí

  1. "Sambisa Forest: Behind Enemy Lines". Daily Trust. 28 January 2022. Retrieved 15 August 2022. 
  2. "How safe is Sambisa forest now?". Vanguard. 20 April 2017. Retrieved 15 August 2022. 
  3. 3.0 3.1 3.2 Kayode, Bodumin (27 April 2014) "Sambisa: Forest of a thousand myths", thenationonlineng.net; retrieved 29 April 2015.
  4. "How safe is Sambisa forest now?". Vanguard. 20 April 2017. Retrieved 15 August 2022. 
  5. "Sambisa Forest From Nature Conservation to Terrorists Haven". thisdaylive.com. 10 May 2014. Archived from the original on 9 May 2015. Retrieved 3 May 2015. 
  6. Kayode, Bodunrin (29 April 2014). "Inside Nigeria's Sambisa forest, the Boko Haram hideout where kidnapped school girls are believed to be held". The Guardian. Retrieved 11 May 2014. 
  7. Okonkwo, Emeka (10 May 2014). "US Marines, Satellite locate missing girls in Sambisa forest". The Herald (Nigeria). Retrieved 11 May 2014. 
  8. "Chibok girls: Kidnapped schoolgirl found in Nigeria". BBC. 18 May 2016. Retrieved 18 May 2016. 
  9. Oladipo, Tomi (24 April 2015) Analysis: Islamic State strengthens ties with Boko Haram, BBC News; retrieved 29 April 2015.