Àrùn oorun àsùnjù
Àrùn oorun àsùnjù | |
---|---|
Àwọn oríṣiríṣi Trypanosoma nínú Ẹ̀jẹ̀ fún àyẹ̀wò | |
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta | |
ICD/CIM-10 | B56. B56. |
ICD/CIM-9 | 086.5 086.5 |
DiseasesDB | 29277 |
MedlinePlus | 001362 |
African trypanosomiasis tàbí àrùn oorun àsùnjù[1] jẹ́ àrùn kòkòrò ajọ̀fẹ́ lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko mìíràn. A má a wáyé nípasẹ̀ kòkòrò àrùn ajọ̀fẹ́ tí ó jẹ́ ara oríṣi ìpín ẹranko tí a npè ní Trypanosoma brucei.[2] Àwọn oríṣi méjì ni ó má a nkó àrùn bá ènìyàn, Trypanosoma brucei gambiense (T.b.g) àti Trypanosoma brucei rhodesiense (T.b.r.).[1] T.b.g ni ó má a nfa méjìdínlógún nínú ọgọrun ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà tí a ti rí rí.[1] Bí eṣinṣin tí ńmú ni sun oorun àsùnjù tí a ńpè ní eṣinṣin tsetse, èyí tí ó ti ní àrùn náà lára tẹ́lẹ̀ rí bá gé ni jẹ ni títàn káàkiri àwọn oríṣi méjèèjì kòkòrò àrùn ajọ̀fẹ́ náà má a ńwáyé, èyí sì wọ́pọ̀ ní àwọn ìgbèríko.[1]
Ní ìbẹ̀rẹ̀, ní ipele èkíní nínú àrùn náà, ibà, orí-fífọ́, ara-yíyún, àti ìrora oríìké-ara a má a wáyé.[1] Èyí a má a bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan sí mẹta tí eṣinṣin náà bá ti gé ni jẹ.[3] Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sí oṣù díẹ̀, ipele kejì a má a bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àìmọ ohun tí ènìyàn ńṣe mọ́, àìlèronú bí ó ti tọ́, àìlègbé ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀, àti àìrí oorun sùn.[1][3] A má a ńṣe ìdánimọ̀ oríṣi àìsàn náà nípa wíwá kòkòrò àrùn ajọ̀fẹ́ náà nínú ẹ̀jẹ̀ tí a pèsè fún àbẹ̀wò tàbí nínú omi-ara tí a gbà láti àwọn oríìké-ara.[3] A má a ń nílò láti fa omi jáde láti inú ọ̀pá-ẹ̀yìn láti lè mọ ìyàtọ̀ laarin ipele èkíní àti èkejì àrùn náà.[3]
Láti dènà bíburújù àrùn náà, a nílò láti ṣe àyẹ̀wò gbogbo àwọn ènìyàn tó wà lábẹ́ ewu níní àrùn náà nípasẹ̀ àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ fún kòkòrò àrùn ajọ̀fẹ́ T.b.g.[1] Ìtọ́jú a má a rọrùn síi nígbàtí a bá ṣàkíyèsi àrùn náà lásìkò àti ṣáájú àkókò tí àwọn ààmì àìsàn iṣan ara yóò bẹ̀rẹ̀ sí farahàn.[1] A má a ńṣe ìtọ́jú ipele èkíní pẹ̀lú àwọn egbògi tí a ńpè ní pentamidine tàbí suramin.[1] Ìtọ́jú ipele kejì a má a wáyé nípasẹ̀ egbògi tí a ńpe ní eflornithine tàbí àdàpọ̀ nifurtimox àti eflornithine fún T.b.g.[3] Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé melarsoprol a má a ṣiṣẹ́ fún méjèèjì, a má a ńsába lòó fún T.b.r. nítorí àwọn ipa mìíràn tí egbògi náà má a ń ní lára ènìyàn.[1]
Àrùn náà a má a wáyé láti ìgbà dé ìgbà ní àwọn agbègbè tí ó wà ní Gúsù Aginjù Sahara ní Afrika, níbití àwọn ènìyàn tí ó wà lábẹ́ ewu ti pọ̀ tó àádọ́rin mílíọ̀nù (70 million) ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndílógójì.[4] Ní ọdún 2010 ó fa ikú àwọn ènìyàn tí ó tó 9,000, èyí tí ó wálẹ̀ láti iye ènìyàn tí ó tó 34,000 ní ọdún 1990.[5] Àwọn ènìyàn tí ó tó 30,000 ni ó ní àrùn náà báyìí, pẹ̀lú àkóràn 7000 titun ní ọdún 2012.[1] Iye tí ó ju ìwọ̀n ọgọsan nínú ọgọrun (80%) lọ lára àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n wà ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kongo.[1] Oríṣi mẹta àjàkálẹ̀ àrùn náà ni ó ti wáyé láìpẹ́: ọ̀kan láti ọdún 1896 sí 1906 ní orílẹ̀-èdè Uganda àti Adágùn omi Kongo nìkan, àti méjì ní ọdún 1920 àti 1970 ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Afrika mìíràn.[1] Àwọn ẹranko mìíràn gẹ́gẹ́ bíi maalu, lè kó àrùn náà, kí wọ́n sì ní àkóràn àìsàn náà.[1]
References
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 1.10 1.11 1.12 1.13 WHO Media centre (June 2013). Fact sheet N°259: Trypanosomiasis, Human African (sleeping sickness). http://www.who.int/mediacentre/factsheets/fs259/en/.
- ↑ Àdàkọ:MedlinePlusEncyclopedia
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 3.4 Kennedy, PG (2013 Feb). "Clinical features, diagnosis, and treatment of human African trypanosomiasis (sleeping sickness).". Lancet neurology 12 (2): 186-94. PMID 23260189.
- ↑ Simarro PP, Cecchi G, Franco JR, Paone M, Diarra A, Ruiz-Postigo JA, Fèvre EM, Mattioli RC, Jannin JG (2012). "Estimating and Mapping the Population at Risk of Sleeping Sickness". PLoS Negl Trop Dis 6 (10): e1859. doi:10.1371/journal.pntd.0001859.
- ↑ Lozano, R (Dec 15, 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010.". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604.