Brenda Fricker
Brenda Fricker | |
---|---|
Fricker at the 62nd Academy Awards in March 1990 | |
Ọjọ́ìbí | 17 Oṣù Kejì 1945 Dublin, Ireland |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 1964–present |
Olólùfẹ́ | Barry Davies (m. 1979; div. 1988) |
Parent(s) |
|
Brenda Fricker (tí a bí ní ọjọ́ kẹta-dín-lógún ọdún 1945) jẹ́ òṣèré Irish kan, tí iṣẹ́ rẹ̀ ti kọjá ọgbọ̀n ọdún ní orí ìtàgé àti lórí ojú ìwòrán. Ó ti farahàn ní fíìmù àti àwọn ipò tẹlifísàn tó ju ọgbọ̀n lọ. Ní ọdún 1990, ó di òṣèré Irish àkọkọ́ láti gba Ààmì-ẹ̀rí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan, tí ó gba ẹ̀bùn náà fún òṣèré Àtìlẹ́yìn tí ó dára jùlọ fún "My left foot" (ní ọdún 1989). Arábìnrin náà tún farahàn nínú àwọn fíìmù bíi "The Field" (ní ọdún 1990), Home Alone 2: Lost in New York (ní ọdún 1992), So I married an Axe Murderer (ní ọdún 1993), Angels in the Outfield (ní ọdún 1994), A time to kill (ní ọdún 1996) , Veronica Guerin (ní ọdún 2003), Inside I'm dancing (ní ọdún 2004) àti Albert Nobbs (ní ọdún 2011).
A bu iyì fún un pẹ̀lú Ààmì ẹ̀rí "Maureen O'Hara Award" ní Keri Film Festival ní ọdún 2008, ẹbùn tí a fún un jẹ́ sí àwọn obìnrin tí ó ní ìlọsíwájú ní ààyè yíyan wọn ní ojú ìwòrán fíìmù. Ní ọdún 2020, ó wà lórí nọ́mbà ẹẹ́rin-dín-lọ́gbọ̀n lórí àkójọ orúkọ ti Irish Times ti àwọn òṣèré fíìmù ńlá ti Ilẹ̀ Ireland.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Fricker ní Dublin, Ilẹ̀ Ireland. Ìyá rẹ̀, "Bina" (née Murphy), jẹ́ olùkọ́ ní ilé ìwé gíga Stratford, àti bàbá rẹ̀, Desmond Frederick Fricker, ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ká ògbìn bíi 'Fred Desmond' olùgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ pẹ̀lú RTE àti oníròyìn fún The Irish Times.
Ṣáájú kí ó tó di òṣèré, Fricker jẹ́ olùrànlọwọ sí olóòtú àwòrán ti Irish Times, pẹ̀lú ìrètí à ti di oníròyìn. Ní ìgbà tó pé ọ̀kàn-dín-lógún ní ọjọ́-orí, ó di òṣèré “nípasẹ̀ àyẹ̀” iṣẹ́ fíìmù ẹ̀yà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú apá kan tí kò ní àpónlé nínú fíìmù ọdún 1964 Human Bondage, tí ó dá lórí ìwé àràmàdà ọdún 1915 nípasẹ̀ W. Somerset Maugham. Ó tún farahàn ní Tolka Row, soap opera àkọ́kọ́ ti Ireland.
Ayé Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fricker lọ́wọ́lọ́wọ́ ńgbé ní Liberties, Dublin. Ó jẹ́ ìyàwó ti tẹ́lẹ̀ sí Olùdarí Barry Davies. Ó sọ pé àwọn ìfẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ajá ọsin rẹ̀, mímú Guinness, kíkà ewì àti ṣíṣeré snooker (ó sọ ní ìgbà kan pé ó ti gbá gbogbo àwọn ará òṣèré ti "My Left Foot". “Mo ṣe adágún-odò sí ẹẹ́ta-dín-lógún nínú wọn, mo sì lu gbogbo wọn,” Brenda wí).